Ọ̀rẹ́ méjì ki aládùúgbò wọn mọ́lẹ̀, wọ́n dú u lọ́rùn láti fi ṣòògùn owó

Awọn afurasi meji kan tọjọ ori wọn ko ju ọdun mejidinlogun lọ, Abdullateef Yakubu ati ọrẹ ẹ, Yakubu Ọlarewaju, ni wọn ti n ṣẹju pẹ lakolo awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ bayii nibi ti wọn ti n ka boroboro latari ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn ki aladuugbo wọn kan Abubakar Babatunde, mọlẹ, wọn si ga a lọrun, wọn si fi ọbẹ du u lọrun nitori lati fi ṣe ogun owo,

BBC News Yoruba gbọ pe ni nnkan bii aago mejila, lọjọ Aje tii ṣe ayajọ ọdun tuntun 2024, ni agbegbe Shao-garage, nijọba ibilẹ ila oorun Ilorun, nipinlẹ Kwara, ni awọn ọrẹ meji yii, Yakubu ati ọrẹ rẹ, Ọlarewaju ti wọn n gbimọ lati ṣe oogun owo ki Abubakar Babatunde mọlẹ, wọn si n du u bii ẹran ewurẹ.

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa sọ pe, ẹgbọn Abubakar ti wọn du lọrun yii lo ba aburo rẹ Abubakar, ninu agbara ẹjẹ ko to di pe wọn gbe e lọ ile iwosan ẹkọṣẹ oniṣegun ti Fasiti Ilọrin, n’ilu Ilọrin, fun itọju.

O ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi mejeeji naa ti wọn si ti n ka boroboro lagọ ọlọpaa.

Ni ọjọ kẹfa osu kinni ọdun 2024 yii ni BBC Yoruba ba alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, sọrọ lori iṣẹlẹ laabi naa.

Adetoun sọ pe ootọ ni, o ni Babatunde, ti o jẹ ẹgbọn fun Abubakar Babatunde lo sọ fun ileesẹ ọlọpaa pe igbe bi aburo ohun ṣe n ke gbajare fun iranlọwọ loun gbọ ti oun si tọpa rẹ lọ.

Bi o ṣe jade ni wọn ferege ti o si sare doola ẹmi aburo rẹ ko to dipe o kan si ọlọpaa lati mu awọn ọdaran naa nitori pe o da wọn mo laduugbo.

Alukoro ọlọpaa fikun ọrọ rẹ pe Abubakar Babatunde n gba itọju lọwọ ni ile iwosan sugbon ko tii le sọrọ si ẹnikẹni.